11 Nitori emi wà pẹlu rẹ, li Oluwa wi, lati gbà ọ: bi emi tilẹ ṣe ipari patapata ni gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi ti tu ọ ka si, sibẹ emi kì yio ṣe ọ pari patapata: ṣugbọn emi o ba ọ wi ni ìwọn, emi kì o jọ̃ rẹ lọwọ li alaijiya.
12 Nitori bayi li Oluwa wi, Ifarapa rẹ jẹ aiwotan, ọgbẹ rẹ si jẹ aijina.
13 Kò si ẹniti o gba ọ̀ran rẹ rò, lati dì i, ọja imularada kò si.
14 Gbogbo awọn olufẹ rẹ ti gbagbe rẹ; nwọn kò tẹle ọ; nitori ìlù ọta li emi o lù ọ, ni inà alaini ãnu, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ pọ si i,
15 Ẽṣe ti iwọ nkigbe nitori ifarapa rẹ? ikãnu rẹ jẹ aiwotan, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ; ẹ̀ṣẹ rẹ si pọ̀ si i, nitorina ni emi ti ṣe ohun wọnyi si ọ.
16 Nitorina gbogbo awọn ti o jẹ ọ, li a o jẹ; ati gbogbo awọn ọta rẹ, olukuluku wọn, ni yio lọ si igbekun: ati awọn ti o kó ọ yio di kikó, ati gbogbo awọn ti o fi ọ ṣe ijẹ li emi o fi fun ijẹ.
17 Nitori emi o fi ọja imularada lè ọ, emi o si wò ọgbẹ rẹ san, li Oluwa wi; nitori nwọn pè ọ li ẹniti a le jade; Sioni, ti ẹnikan kò ṣafẹri rẹ̀!