11 Nitori Oluwa ti tú Jakobu silẹ, o si rà a pada li ọwọ awọn ti o li agbara jù u lọ.
12 Njẹ, nwọn o wá, nwọn o si kọrin ni ibi giga Sioni, nwọn o si jumọ lọ sibi ore Oluwa, ani fun alikama, ati fun ọti-waini, ati fun ororo, ati fun ẹgbọrọ agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran: ọkàn wọn yio si dabi ọgbà ti a bomi rin; nwọn kì yio si kãnu mọ rara.
13 Nigbana ni wundia yio yọ̀ ninu ijó, pẹlu ọdọmọkunrin ati arugbo ṣọkan pọ̀: nitori emi o sọ ọ̀fọ wọn di ayọ̀, emi o si tù wọn ninu, emi o si mu wọn yọ̀ lẹhin ikãnu wọn.
14 Emi o si fi sisanra tẹ ọkàn awọn alufa lọrun, ore mi yio si tẹ awọn enia mi lọrun, li Oluwa wi.
15 Bayi li Oluwa wi, Ni Rama li a gbọ́ ohùnrere, ẹkún kikoro; Rakeli nsọkun fun awọn ọmọ rẹ̀, kò gbipẹ nitori awọn ọmọ rẹ̀, nitoripe nwọn kò si.
16 Bayi li Oluwa wi; Dá ohùn rẹ duro ninu ẹkun, ati oju rẹ ninu omije: nitori iṣẹ rẹ ni ère, li Oluwa wi, nwọn o si pada wá lati ilẹ ọta.
17 Ireti si wà ni igbẹhin rẹ, li Oluwa wi, pe awọn ọmọ rẹ yio pada si agbegbe wọn.