25 Nitori emi tù ọkàn alãrẹ ninu, emi si ti tẹ gbogbo ọkàn ikãnu lọrun.
26 Lori eyi ni mo ji, mo si wò; õrun mi si dùn mọ mi.
27 Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbin ile Israeli ati Judah ni irugbin enia, ati irugbin ẹran.
28 Yio si ṣe, pe gẹgẹ bi emi ti ṣọ́ wọn, lati fà tu, ati lati fa lulẹ, ati lati wo lulẹ, ati lati parun, ati lati pọnloju, bẹ̃ni emi o ṣọ́ wọn, lati kọ́, ati lati gbìn, li Oluwa wi.
29 Li ọjọ wọnni, nwọn kì yio wi mọ pe, Awọn baba ti jẹ eso ajara aipọn, ehín si ti kan awọn ọmọ.
30 Ṣugbọn olukuluku ni yio kú nitori aiṣedede rẹ̀, olukuluku ti o jẹ eso ajara-aipọn ni ehín yio kan.
31 Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o ba ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun.