36 Bi ilana wọnyi ba yẹ̀ kuro niwaju mi, li Oluwa wi, njẹ iru-ọmọ Israeli pẹlu yio dẹkun lati ma jẹ orilẹ-ède niwaju mi lailai.
37 Bayi li Oluwa wi, Bi a ba le wọ̀n ọrun loke, ti a si le wá ipilẹ aiye ri nisalẹ, emi pẹlu yio ta iru-ọmọ Israeli nù nitori gbogbo eyiti nwọn ti ṣe, li Oluwa wi.
38 Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti a o kọ́ ilu na fun Oluwa lati ile-iṣọ Hananeeli de ẹnu-bode igun odi.
39 Okùn ìwọn yio si nà jade siwaju lẹba rẹ̀ lori oke Garebi, yio si lọ yi Goati ka.
40 Ati gbogbo afonifoji okú, ati ti ẽru, ati gbogbo oko titi de odò Kidroni, titi de igun ẹnubode-ẹṣin niha ilà-õrun, ni yio jẹ mimọ́ fun Oluwa; a kì yio fà a tu, bẹ̃ni a kì yio si wó o lulẹ mọ lailai.