1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa li ọdun kẹwa Sedekiah, ọba Juda, eyiti o jẹ ọdun kejidilogun ti Nebukadnessari.
2 Nigbana ni ogun ọba Babeli ha Jerusalemu mọ: a si se Jeremiah woli mọ agbala ile túbu, ti o wà ni ile ọba Juda.
3 Nitori Sedekiah, ọba Judah, ti se e mọ, wipe, Ẽṣe ti iwọ sọtẹlẹ, ti o si wipe, Bayi li Oluwa wi, wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ ọba Babeli, on o si ko o;
4 Ati Sedekiah, ọba Juda, kì yio bọ́ li ọwọ awọn ara Kaldea, ṣugbọn a o fi i le ọwọ ọba Babeli, Lõtọ, yio si ba a sọ̀rọ li ojukoju, oju rẹ̀ yio si ri oju rẹ̀.
5 On o si mu Sedekiah lọ si Babeli, nibẹ ni yio si wà titi emi o fi bẹ̀ ẹ wò, li Oluwa wi; bi ẹnyin tilẹ ba awọn ará Kaldea jà, ẹnyin kì yio ṣe rere.
6 Jeremiah si wipe, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,
7 Wò o, Hanameeli, ọmọ Ṣallumu, ẹ̀gbọn rẹ, yio tọ̀ ọ wá, wipe, Iwọ rà oko mi ti o wà ni Anatoti: nitori titọ́ irasilẹ jẹ tirẹ lati rà a.