8 Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, si tọ̀ mi wá li agbala ile túbu gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, o si wi fun mi pe, Jọ̃, ra oko mi, ti o wà ni Anatoti, ti o wà ni ilẹ Benjamini: nitori titọ́ ogun rẹ̀ jẹ tirẹ, ati irasilẹ jẹ tirẹ; rà a fun ara rẹ. Nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi li ọ̀rọ Oluwa.
9 Emi si rà oko na lọwọ Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, ti o wà ni Anatoti, mo si wọ̀n owo fun u, ṣekeli meje ati ìwọn fadaka mẹwa.
10 Mo si kọ ọ sinu iwe, mo si di i, mo si pè awọn ẹlẹri si i, mo si wọ̀n owo na ninu òṣuwọn.
11 Mo si mu iwe rirà na eyiti a dí nipa aṣẹ ati ilana, ati eyiti a ṣi silẹ.
12 Mo si fi iwe rirà na fun Baruki, ọmọ Neriah, ọmọ Masseiah, li oju Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, ati niwaju awọn ẹlẹri ti o kọ orukọ wọn si iwe rirà na, niwaju gbogbo ọkunrin Juda ti o joko ni àgbala ile túbu.
13 Mo si paṣẹ fun Baruki li oju wọn wipe,
14 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wipe, Mu iwe wọnyi, iwe rirà yi, ti a dí, ati iwe yi ti a ṣi silẹ; ki o si fi wọn sinu ikoko, ki nwọn ki o le wà li ọjọ pupọ.