10 Njẹ nigbati gbogbo awọn ijoye, ati gbogbo enia, ti nwọn dá majẹmu yi, gbọ́ pe ki olukuluku ki o jẹ ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku, iranṣẹbinrin rẹ̀, lọ lọfẹ, ki ẹnikan má mu wọn sin wọn mọ, nwọn gbọ́, nwọn si jọ̃ wọn lọwọ.
11 Ṣugbọn lẹhin na nwọn yi ọkàn pada, nwọn si mu ki awọn iranṣẹkunrin ati awọn iranṣẹbinrin, awọn ẹniti nwọn ti jẹ ki o lọ lọfẹ, ki o pada, nwọn si mu wọn sin bi iranṣẹkunrin ati bi iranṣẹbinrin.
12 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, wipe,
13 Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi, pe; Emi ba awọn baba nyin dá majẹmu li ọjọ ti emi mu wọn jade lati ilẹ Egipti, kuro ninu oko-ẹrú, wipe,
14 Li opin ọdọdun meje ki olukuluku enia jẹ ki arakunrin rẹ̀ ki o lọ, ani ara Heberu ti o ta ara rẹ̀ fun ọ; yio si sìn ọ li ọdun mẹfa, nigbana ni iwọ o jẹ ki o lọ lọfẹ lọdọ rẹ: ṣugbọn awọn baba nyin kò gbọ́ temi, bẹ̃ni wọn ko tẹti wọn silẹ.
15 Ẹnyin si yi ọkàn pada loni, ẹ si ti ṣe eyi ti o tọ li oju mi, ni kikede omnira, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀; ẹnyin si ti dá majẹmu niwaju mi ni ile ti a fi orukọ mi pè:
16 Ṣugbọn ẹnyin yipada, ẹ si sọ orukọ mi di ẽri, olukuluku enia si mu ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku enia iranṣẹbinrin rẹ̀, ti on ti sọ di omnira ni ifẹ wọn, ki o pada, ẹnyin si mu wọn sìn lati jẹ iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, fun nyin.