14 Ọ̀rọ Jonadabu, ọmọ Rekabu, ti o pa laṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀, pe, ki nwọn ki o má mu ọti-waini, ni a mu ṣẹ; nwọn kò si mu ọti-waini titi di oni yi. Nitoriti nwọn gbọ́ ofin baba wọn, emi si ti nsọ̀rọ fun nyin, emi dide ni kutukutu, emi nsọ: ṣugbọn ẹnyin kò fetisi ti emi.
15 Emi si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli, si nyin pẹlu, emi dide ni kutukutu, mo ran wọn wipe, Ẹ yipada nisisiyi, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun iṣe nyin ṣe rere, ki ẹ máṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin lati sin wọn, ẹnyin o si ma gbe ilẹ na ti mo ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin; ṣugbọn ẹnyin kò tẹ eti nyin, bẹ̃ni ẹnyin kò si gbọ́ temi.
16 Lõtọ awọn ọmọ Jonadabu, ọmọ Rekabu, pa ofin baba wọn mọ, ti o pa laṣẹ fun wọn; ṣugbọn awọn enia yi kò gbọ́ ti emi:
17 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, Wò o, emi o mu wá sori Juda, ati sori gbogbo olugbe Jerusalemu, gbogbo ibi ti emi ti sọ si wọn; nitori ti emi ti ba wọn sọ̀rọ, nwọn kò si gbọ́; mo si ti pè wọn, nwọn kò si dahùn.
18 Jeremiah si wi fun ile awọn ọmọ Rekabu pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitori ti ẹnyin gbà ofin Jonadabu, baba nyin gbọ́, ti ẹnyin si pa gbogbo ilana rẹ̀ mọ, ti ẹ si ṣe gẹgẹ bi eyi ti o ti palaṣẹ fun nyin:
19 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Jonadabu, ọmọ Rekabu kì yio fẹ ọkunrin kan kù lati duro niwaju mi lailai.