7 Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ kọ́ ile, tabi ki ẹ fun irugbin, tabi ki ẹ gbin ọgba-àjara, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ ni; ṣugbọn ni gbogbo ọjọ nyin li ẹnyin o ma gbe inu agọ; ki ẹnyin ki o le wà li ọjọ pupọ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nṣe atipo.
8 Bayi li awa gbà ohùn Jonadabu, ọmọ Rekabu, baba wa gbọ́ ninu gbogbo eyiti o palaṣẹ fun wa, ki a má mu ọti-waini ni gbogbo ọjọ wa, awa, awọn aya wa, awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa;
9 Ati ki a má kọ ile lati gbe; bẹ̃ni awa kò ni ọgba-ajara, tabi oko, tabi ohùn ọgbin.
10 Ṣugbọn awa ngbe inu agọ, a si gbọran, a si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jonadabu, baba wa, palaṣẹ fun wa.
11 O si ṣe, nigbati Nebukadnessari, ọba Babeli, goke wá si ilẹ na, ni awa wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si Jerusalemu, nitori ibẹ̀ru ogun awọn ara Kaldea, ati nitori ibẹ̀ru ogun awọn ara Siria: bẹ̃ni awa ngbe Jerusalemu.
12 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá wipe:
13 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Lọ, ki o si sọ fun awọn ọkunrin Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu pe, Ẹnyin kì yio ha gbà ẹkọ lati feti si ọ̀rọ mi? li Oluwa wi.