19 Nigbana ni awọn ijoye sọ fun Baruku pe, Lọ, fi ara rẹ pamọ, iwọ ati Jeremiah; má si jẹ ki ẹnikan mọ̀ ibi ti ẹnyin wà.
20 Nwọn si wọle tọ̀ ọba lọ ninu àgbala, ṣugbọn nwọn fi iwe-kiká na pamọ si iyara Eliṣama, akọwe, nwọn si sọ gbogbo ọ̀rọ na li eti ọba.
21 Ọba si rán Jehudu lati lọ mu iwe-kiká na wá: on si mu u jade lati inu iyara Eliṣama, akọwe. Jehudu si kà a li eti ọba, ati li eti gbogbo awọn ijoye, ti o duro tì ọba.
22 Ọba si ngbe ile igba-otutu li oṣu kẹsan: ina si njo niwaju rẹ̀ ninu idana.
23 O si ṣe, nigbati Jehudu ti kà ewe mẹta tabi mẹrin, ọba fi ọbẹ ke iwe na, o si sọ ọ sinu iná ti o wà ninu idaná, titi gbogbo iwe-kiká na fi joná ninu iná ti o wà lori idaná.
24 Sibẹ nwọn kò warìri, nwọn kò si fa aṣọ wọn ya, ani ọba, ati gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ ti o gbọ́ gbogbo ọ̀rọ wọnyi.
25 Ṣugbọn Elnatani ati Delaiah ati Gemariah bẹbẹ lọdọ ọba ki o máṣe fi iwe-kiká na joná, kò si fẹ igbọ́ ti wọn.