11 O si ṣe, nigbati ogun awọn ara Kaldea goke lọ kuro ni Jerusalemu nitori ogun Farao,
12 Ni Jeremiah jade kuro ni Jerusalemu lati lọ si ilẹ Benjamini lati pin ini lãrin awọn enia.
13 Nigbati o si wà li ẹnu-bode Benjamini, balogun iṣọ kan wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Irijah, ọmọ Ṣelemiah, ọmọ Hananiah; on si mu Jeremiah woli, wipe, Iwọ nsa tọ̀ awọn ara Kaldea lọ.
14 Jeremiah si wipe: Eke! emi kò sa tọ awọn ara Kaldea lọ. Ṣugbọn kò gbọ́ tirẹ̀: bẹ̃ni Irijah mu Jeremiah, o si mu u tọ̀ awọn ijoye wá.
15 Nitorina ni awọn ijoye ṣe binu si Jeremiah, nwọn si lù u, nwọn si fi sinu tubu ni ile Jonatani, akọwe; nitori nwọn ti fi eyi ṣe ile túbu.
16 Bẹ̃ni Jeremiah lọ inu ile-túbu ati inu iyara ṣiṣokunkun. Jeremiah si wà nibẹ li ọjọ pupọ;
17 Nigbana ni Sedekiah, ọba ranṣẹ pè e: ọba si bere lọwọ rẹ̀ nikọkọ ni ile rẹ̀, o si wipe, Ọ̀rọ ha wà lati ọdọ Oluwa? Jeremiah si wipe, O wà: o wi pe, nitori a o fi ọ le ọwọ ọba Babeli.