13 Nigbati o si wà li ẹnu-bode Benjamini, balogun iṣọ kan wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Irijah, ọmọ Ṣelemiah, ọmọ Hananiah; on si mu Jeremiah woli, wipe, Iwọ nsa tọ̀ awọn ara Kaldea lọ.
14 Jeremiah si wipe: Eke! emi kò sa tọ awọn ara Kaldea lọ. Ṣugbọn kò gbọ́ tirẹ̀: bẹ̃ni Irijah mu Jeremiah, o si mu u tọ̀ awọn ijoye wá.
15 Nitorina ni awọn ijoye ṣe binu si Jeremiah, nwọn si lù u, nwọn si fi sinu tubu ni ile Jonatani, akọwe; nitori nwọn ti fi eyi ṣe ile túbu.
16 Bẹ̃ni Jeremiah lọ inu ile-túbu ati inu iyara ṣiṣokunkun. Jeremiah si wà nibẹ li ọjọ pupọ;
17 Nigbana ni Sedekiah, ọba ranṣẹ pè e: ọba si bere lọwọ rẹ̀ nikọkọ ni ile rẹ̀, o si wipe, Ọ̀rọ ha wà lati ọdọ Oluwa? Jeremiah si wipe, O wà: o wi pe, nitori a o fi ọ le ọwọ ọba Babeli.
18 Pẹlupẹlu Jeremiah sọ fun Sedekiah, ọba, pe; Ẹṣẹ wo ni mo ṣẹ̀ ọ, tabi awọn iranṣẹ rẹ, tabi awọn enia yi, ti ẹnyin fi mi sinu ile-túbu?
19 Nibo ni awọn woli nyin ha wà nisisiyi, awọn ti nsọtẹlẹ fun nyin, wipe, Ọba Babeli kì yio wá sọdọ nyin ati si ilẹ yi?