15 Nitorina ni awọn ijoye ṣe binu si Jeremiah, nwọn si lù u, nwọn si fi sinu tubu ni ile Jonatani, akọwe; nitori nwọn ti fi eyi ṣe ile túbu.
16 Bẹ̃ni Jeremiah lọ inu ile-túbu ati inu iyara ṣiṣokunkun. Jeremiah si wà nibẹ li ọjọ pupọ;
17 Nigbana ni Sedekiah, ọba ranṣẹ pè e: ọba si bere lọwọ rẹ̀ nikọkọ ni ile rẹ̀, o si wipe, Ọ̀rọ ha wà lati ọdọ Oluwa? Jeremiah si wipe, O wà: o wi pe, nitori a o fi ọ le ọwọ ọba Babeli.
18 Pẹlupẹlu Jeremiah sọ fun Sedekiah, ọba, pe; Ẹṣẹ wo ni mo ṣẹ̀ ọ, tabi awọn iranṣẹ rẹ, tabi awọn enia yi, ti ẹnyin fi mi sinu ile-túbu?
19 Nibo ni awọn woli nyin ha wà nisisiyi, awọn ti nsọtẹlẹ fun nyin, wipe, Ọba Babeli kì yio wá sọdọ nyin ati si ilẹ yi?
20 Nitorina gbọ́ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, oluwa mi, ọba, jẹ ki ẹ̀bẹ mi, emi bẹ̀ ọ, ki o wá si iwaju rẹ; ki iwọ ki o má jẹ ki emi pada si ile Jonatani akọwe, ki emi má ba kú nibẹ.
21 Sedekiah, ọba, si paṣẹ pe ki nwọn ki o fi Jeremiah pamọ sinu agbala ile-túbu, ati pe ki nwọn ki o ma fun u ni iṣu akara kọ̃kan lojojumọ, lati ita awọn alakara, titi gbogbo akara fi tan ni ilu. Jeremiah si wà li agbala ile-túbu.