5 Ṣugbọn ogun awọn ara Kaldea lepa wọn, nwọn si ba Sedekiah, ọba, ni pẹtẹlẹ Jeriko; nigbati nwọn si mu u, nwọn mu u goke wá sọdọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ni Ribla ni ilẹ Hamati, nibiti o sọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.
6 Nigbana ni ọba Babeli pa awọn ọmọ Sedekiah ni Ribla, niwaju rẹ̀; ọba Babeli si pa gbogbo awọn ọlọla Juda pẹlu.
7 Pẹlupẹlu o fọ Sedekiah li oju, o si fi ẹ̀wọn dè e, lati mu u lọ si Babeli.
8 Awọn ara Kaldea si fi ile ọba ati ile awọn enia joná, nwọn si wó odi Jerusalemu lulẹ.
9 Nebusaradani, balogun iṣọ, si kó iyokù awọn enia ti o kù ni ilu ni igbekun lọ si Babeli, pẹlu awọn ti o ti ya lọ, ti o ya sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn enia iyokù ti o kù.
10 Ṣugbọn Nebusaradani, balogun iṣọ, si mu diẹ ninu awọn enia, ani awọn talaka ti kò ni nkan rara, joko ni ilẹ Juda, o si fi ọgba-àjara ati oko fun wọn li àkoko na.
11 Nebukadnessari, ọba Babeli, si paṣẹ fun Nebusaradani, balogun iṣọ, niti Jeremiah, wipe,