1 O si ṣe, nigbati Jeremiah pari ọ̀rọ isọ fun gbogbo awọn enia, ani gbogbo ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun wọn, eyiti Oluwa Ọlọrun wọn ti rán a si wọn, ani gbogbo ọ̀rọ wọnyi.
2 Nigbana ni Asariah, ọmọ Hoṣaiah, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn agberaga enia, wi fun Jeremiah pe, Iwọ ṣe eke! Oluwa, Ọlọrun wa, kò ran ọ lati wipe, Ẹ má lọ si Egipti lati ṣatipo nibẹ:
3 Ṣugbọn Baruku, ọmọ Neriah, li o fi ọ̀rọ si ọ li ẹnu si wa, nitori lati fi wa le awọn ara Kaldea lọwọ, lati pa wa ati lati kó wa ni igbekun lọ si Babeli.
4 Bẹ̃ni Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun, ati gbogbo awọn enia, kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, lati má gbe ilẹ Juda,
5 Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun, si mu gbogbo iyokù Juda, ti nwọn pada lati gbogbo orilẹ-ède wá, ni ibi ti a ti le wọn si, lati ma gbe ilẹ Juda;