14 Ẹ sọ ọ ni Egipti, ki ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Migdoli, ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Nofu ati Tafanesi: ẹ wipe, duro lẹsẹsẹ, ki o si mura, nitori idà njẹrun yi ọ kakiri.
15 Ẽṣe ti a fi gbá awọn akọni rẹ lọ? nwọn kò duro, nitori Oluwa le wọn.
16 A sọ awọn ti o kọsẹ di pupọ, lõtọ, ẹnikini ṣubu le ori ẹnikeji: nwọn si wipe, Dide, ẹ jẹ ki a pada lọ sọdọ awọn enia wa, ati si ilẹ ti a bi wa, kuro lọwọ idá aninilara.
17 Nwọn kigbe nibẹ; Farao, ọba Egipti ti ṣegbe: on ti kọja akoko ti a dá!
18 Bi emi ti wà, li Ọba, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, nitõtọ gẹgẹ bi Tabori lãrin awọn oke, ati gẹgẹ bi Karmeli lẹba okun, bẹ̃ni on o de.
19 Iwọ, ọmọbinrin ti ngbe Egipti, pèse ohun-èlo ìrin-ajo fun ara rẹ: nitori Nofu yio di ahoro, a o si fi joná, laini olugbe.
20 Ẹgbọrọ malu ti o dara pupọ ni Egipti, lõtọ, iparun de, o de lati ariwa!