24 Oju yio tì ọmọbinrin Egipti; a o fi i le ọwọ awọn enia ariwa.
25 Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wipe; Wò o, emi o bẹ̀ Amoni ti No, ati Farao, ati Egipti wò, pẹlu awọn ọlọla wọn, ati awọn ọba wọn; ani Farao ati gbogbo awọn ti o gbẹkẹ le e:
26 Emi o si fi wọn le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn, ati le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ati le ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀: lẹhin na, a o si mã gbe inu rẹ̀, gẹgẹ bi ìgba atijọ, li Oluwa wi.
27 Ṣugbọn iwọ má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, má si fòya, iwọ Israeli: nitori, wo o, emi o gbà ọ là lati okere wá, ati iru-ọmọ rẹ lati ilẹ ìgbekun wọn; Jakobu yio si pada, yio si wà ni isimi, yio si gbe jẹ, ẹnikan kì o si dẹ̀ru bà a.
28 Iwọ má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu rẹ; nitori emi o ṣe opin patapata ni gbogbo awọn orilẹ-ède, nibiti emi ti le ọ si: ṣugbọn emi kì o ṣe ọ li opin patapata, ṣugbọn emi o ba ọ wi ni ìwọn; sibẹ emi kì yio jọ̃ rẹ lọwọ li alaijiya.