39 Ẹ hu, pe, bawo li a ti wo o lulẹ! bawo ni Moabu ti fi itiju yi ẹhin pada! bẹ̃ni Moabu yio di ẹ̀gan ati idãmu si gbogbo awọn ti o yi i kakiri.
40 Nitori bayi li Oluwa wi; Wò o, on o fò gẹgẹ bi idi, yio si nà iyẹ rẹ̀ lori Moabu.
41 A kó Kerioti, a si kó awọn ilu olodi, ati ọkàn awọn akọni Moabu li ọjọ na yio dabi ọkàn obinrin ninu irọbi rẹ̀.
42 A o si pa Moabu run lati má jẹ orilẹ-ède, nitoripe o ti gberaga si Oluwa.
43 Ẹ̀ru, ati ọ̀fin, ati okùn-didẹ, yio wà lori rẹ iwọ olugbe Moabu, li Oluwa wi.
44 Ẹniti o ba sa fun ẹ̀ru yio ṣubu sinu ọ̀fin; ati ẹniti o ba jade kuro ninu ọ̀fin ni a o mu ninu okùn-didẹ: nitori emi o mu wá sori rẹ̀, ani sori Moabu, ọdun ibẹ̀wo wọn, li Oluwa wi.
45 Awọn ti o sá, duro li aini agbara labẹ ojiji Heṣboni: ṣugbọn iná yio jade wá lati Heṣboni, ati ọwọ-iná lati ãrin Sihoni, yio si jẹ ilẹ Moabu run, ati agbari awọn ọmọ ahoro.