6 Ẹ sa, ẹ gbà ẹmi nyin là, ki ẹ si dabi alaini li aginju!
7 Njẹ nitoriti iwọ ti gbẹkẹle iṣẹ ọwọ rẹ ati le iṣura rẹ, a o si kó iwọ pẹlu: Kemoṣi yio si jumọ lọ si ìgbekun, pẹlu awọn alufa rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀.
8 Awọn oluparun yio wá sori olukuluku ilu, ilu kan kì o si bọ́: afonifoji pẹlu yio ṣegbe, a o si pa pẹtẹlẹ run, gẹgẹ bi Oluwa ti wi.
9 Fi iyẹ fun Moabu, ki o ba le fò ki o si lọ, ilu rẹ̀ yio si di ahoro, laisi ẹnikan lati gbe inu rẹ̀.
10 Ifibu li ẹniti o ṣe iṣẹ Oluwa ni imẹlẹ, ifibu si li ẹniti o dá idà rẹ̀ duro kuro ninu ẹjẹ.
11 Moabu ti wà ni irọra lati igba ewe rẹ̀ wá, o si ti silẹ lori gẹdẹgẹdẹ̀ bi ọtiwaini, a kò si ti dà a lati inu ohun-elo, de ohun-elo bẹ̃ni kò ti ilọ si igbekun: nitorina itọwò rẹ̀ wà ninu rẹ̀, õrun rẹ̀ kò si pada.
12 Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o rán awọn atẹni-sapakan si i, ti o si tẹ̀ ẹ sapakan, nwọn o si sọ gbogbo ohun-elo rẹ̀ di ofo, nwọn o si fọ ìgo wọn.