8 Awọn oluparun yio wá sori olukuluku ilu, ilu kan kì o si bọ́: afonifoji pẹlu yio ṣegbe, a o si pa pẹtẹlẹ run, gẹgẹ bi Oluwa ti wi.
9 Fi iyẹ fun Moabu, ki o ba le fò ki o si lọ, ilu rẹ̀ yio si di ahoro, laisi ẹnikan lati gbe inu rẹ̀.
10 Ifibu li ẹniti o ṣe iṣẹ Oluwa ni imẹlẹ, ifibu si li ẹniti o dá idà rẹ̀ duro kuro ninu ẹjẹ.
11 Moabu ti wà ni irọra lati igba ewe rẹ̀ wá, o si ti silẹ lori gẹdẹgẹdẹ̀ bi ọtiwaini, a kò si ti dà a lati inu ohun-elo, de ohun-elo bẹ̃ni kò ti ilọ si igbekun: nitorina itọwò rẹ̀ wà ninu rẹ̀, õrun rẹ̀ kò si pada.
12 Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o rán awọn atẹni-sapakan si i, ti o si tẹ̀ ẹ sapakan, nwọn o si sọ gbogbo ohun-elo rẹ̀ di ofo, nwọn o si fọ ìgo wọn.
13 Moabu yio si tiju nitori Kemoṣi, gẹgẹ bi ile Israeli ti tiju nitori Beteli, igbẹkẹle wọn.
14 Ẹnyin ha ṣe wipe, akọni ọkunrin ni awa, alagbara fun ogun?