22 Ẹ kò ha bẹ̀ru mi; li Oluwa wi, ẹ kì yio warìri niwaju mi, ẹniti o fi yanrin ṣe ipãla okun, opin lailai ti kò le rekọja: ìgbì rẹ̀ kọlu u, kò si le bori rẹ̀, o pariwo, ṣugbọn kò lè re e kọja?
23 Ṣugbọn enia yi ni aiya isàgun ati iṣọtẹ si, nwọn sọ̀tẹ, nwọn si lọ.
24 Bẹ̃ni nwọn kò wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a bẹ̀ru Oluwa Ọlọrun wa wayi, ẹniti o fun wa ni òjo akọrọ ati arọkuro ni igba rẹ̀: ti o fi ọ̀sẹ ikore ti a pinnu pamọ fun wa.
25 Aiṣedede nyin ti yi gbogbo ohun wọnyi pada, ati ẹ̀ṣẹ nyin ti fà ohun rere sẹhin kuro lọdọ nyin.
26 Nitori lãrin enia mi ni a ri enia ìka, nwọn wò kakiri, bi biba ẹniti ndẹ ẹiyẹ, nwọn dẹ okùn nwọn mu enia.
27 Bi àgo ti o kún fun ẹiyẹ, bẹ̃ni ile wọn kún fun ẹ̀tan, nitorina ni nwọn ṣe di nla, nwọn si di ọlọrọ̀.
28 Nwọn sanra, nwọn ndán, pẹlupẹlu nwọn rekọja ni ìwa-buburu, nwọn kò ṣe idajọ, nwọn kò dajọ ọ̀ran alainibaba, ki nwọn le ri rere; nwọn kò si dajọ are awọn talaka.