26 Ẹ wá sori rẹ̀ lati opin gbogbo, ṣi ile iṣura rẹ̀ silẹ: ẹ kó o jọ bi òkiti, ki ẹ si yà a sọtọ fun iparun, ẹ máṣe fi iyokù silẹ fun u!
27 Pa gbogbo awọn akọ-malu rẹ̀! nwọn o lọ si ibi pipa: ègbe ni fun wọn! nitori ọjọ wọn de, àkoko ibẹwo wọn.
28 Ohùn awọn ti o salọ, ti o si sala lati ilẹ Babeli wá, lati kede igbẹsan Oluwa Ọlọrun wa ni Sioni, igbẹsan tempili rẹ̀!
29 Pè ọ̀pọlọpọ enia, ani gbogbo tafatafa, sori Babeli, ẹ dótì i yikakiri; má jẹ ki ẹnikan sala: san fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o ti ṣe, ẹ ṣe bẹ̃ si i, nitoriti o ti gberaga si Oluwa, si Ẹni-Mimọ Israeli.
30 Nitorina ni awọn ọdọmọdekunrin rẹ̀ yio ṣubu ni ita rẹ̀, ati gbogbo awọn ologun rẹ̀ li a o ke kuro li ọjọ na, li Oluwa wi.
31 Wò o, emi dojukọ ọ! iwọ agberaga, li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, wi: nitori ọjọ rẹ de, àkoko ti emi o bẹ̀ ọ wò.
32 Agberaga yio kọsẹ, yio si ṣubu, ẹnikan kì o si gbe e dide: emi o si da iná ni ilu rẹ̀, yio si jo gbogbo ohun ti o yi i kakiri.