31 Wò o, emi dojukọ ọ! iwọ agberaga, li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, wi: nitori ọjọ rẹ de, àkoko ti emi o bẹ̀ ọ wò.
32 Agberaga yio kọsẹ, yio si ṣubu, ẹnikan kì o si gbe e dide: emi o si da iná ni ilu rẹ̀, yio si jo gbogbo ohun ti o yi i kakiri.
33 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Juda li a jumọ pọn loju pọ̀: gbogbo awọn ti o kó wọn ni ìgbekun si di wọn mu ṣinṣin; nwọn kọ̀ lati jọ wọn lọwọ lọ.
34 Ṣugbọn Olurapada wọn lagbara; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀: ni jijà yio gba ijà wọn jà! ki o le mu ilẹ na simi, ki o si mu awọn olugbe Babeli wariri.
35 Ida lori awọn ara Kaldea, li Oluwa wi, ati lori awọn olugbe Babeli, ati lori awọn ijoye rẹ̀, ati lori awọn ọlọgbọn rẹ̀?
36 Idà lori awọn ahalẹ nwọn o si ṣarán: idà lori awọn alagbara rẹ̀; nwọn o si damu.
37 Idà lori awọn ẹṣin rẹ̀, ati lori awọn kẹ̀kẹ ati lori gbogbo awọn àjeji enia ti o wà lãrin rẹ̀; nwọn o si di obinrin: idà lori iṣura rẹ̀; a o si kó wọn lọ.