4 Li ọjọ wọnni ati li àkoko na, li Oluwa wi, awọn ọmọ Israeli yio jumọ wá, awọn, ati awọn ọmọ Juda, nwọn o ma lọ tẹkúntẹkún: nwọn o lọ, nwọn o si ṣafẹri Oluwa Ọlọrun wọn.
5 Nwọn o ma bère ọ̀na Sioni, oju wọn yio si yi sibẹ, nwọn o wá, nwọn o darapọ mọ Oluwa ni majẹmu aiyeraiye, ti a kì yio gbagbe.
6 Awọn enia mi ti jẹ agbo-agutan ti o sọnu: awọn oluṣọ-agutan wọn ti jẹ ki nwọn ṣina, nwọn ti jẹ ki nwọn rìn kiri lori oke: nwọn ti lọ lati ori oke nla de oke kekere, nwọn ti gbagbe ibusun wọn.
7 Gbogbo awọn ti o ri wọn, ti pa wọn jẹ: awọn ọta wọn si wipe, Awa kò jẹbi, nitoripe nwọn ti ṣẹ̀ si Oluwa ibugbe ododo, ati ireti awọn baba wọn, ani Oluwa.
8 Ẹ salọ kuro li ãrin Babeli, ẹ si jade kuro ni ilẹ awọn ara Kaldea, ki ẹ si jẹ bi obukọ niwaju agbo-ẹran.
9 Nitori, wò o, emi o gbe dide, emi o si mu apejọ awọn orilẹ-ède nla lati ilẹ ariwa wá sori Babeli: nwọn o si tẹgun si i, lati ibẹ wá li a o si ti mu u: ọfa wọn yio dabi ti akọni amoye; ọkan kì yio pada li asan.
10 Kaldea yio si di ikogun: gbogbo awọn ti o fi ṣe ikogun ni a o tẹ́ lọrùn, li Oluwa wi.