1 BAYI li Oluwa wi: wò o, emi o rú afẹfẹ iparun soke si Babeli, ati si awọn ti ngbe ãrin awọn ti o dide si mi;
2 Emi o si rán awọn alatẹ si Babeli, ti yio fẹ ẹ, nwọn o si sọ ilẹ rẹ̀ di ofo: nitori li ọjọ wahala ni nwọn o wà lọdọ rẹ̀ yikakiri.
3 Jẹ ki tafatafa fà ọrun rẹ̀ si ẹniti nfà ọrun, ati si ẹniti o nṣogo ninu ẹ̀wu irin rẹ̀: ẹ má si ṣe dá awọn ọdọmọdekunrin rẹ̀ si, ẹ run gbogbo ogun rẹ̀ patapata.
4 Awọn ti a pa yio si ṣubu ni ilẹ awọn ara Kaldea, awọn ti a gun li ọ̀kọ, yio si ṣubu ni ita rẹ̀.
5 Nitori Israeli ati Juda, kì iṣe opó niwaju Ọlọrun wọn, niwaju Oluwa, awọn ọmọ-ogun; nitori ilẹ wọn (Babeli) ti kún fun ẹbi si Ẹni-Mimọ Israeli.
6 Ẹ salọ kuro lãrin Babeli, ki olukuluku enia ki o si gbà ọkàn rẹ̀ là: ki a máṣe ke nyin kuro ninu aiṣedede rẹ̀; nitori eyi li àkoko igbẹsan fun Oluwa; yio san ère iṣẹ fun u.