22 Emi o si fi ọ fọ ọkunrin ati obinrin tũtu; emi o si fi ọ fọ arugbo ati ọmọde tũtu; emi o si fi ọ fọ ọdọmọkunrin ati wundia tũtu;
23 Emi o si fi ọ fọ oluṣọ-agutan ati agbo-ẹran rẹ̀ tũtu, emi o si fi ọ fọ àgbẹ ati àjaga-malu rẹ̀ tũtu; emi o si fi ọ fọ awọn balẹ ati awọn ijoye tũtu.
24 Ṣugbọn emi o si san fun Babeli ati fun gbogbo awọn olugbe Kaldea gbogbo ibi wọn, ti nwọn ti ṣe ni Sioni li oju nyin, li Oluwa wi.
25 Wo o, emi dojukọ ọ, iwọ oke ipanirun! li Oluwa wi, ti o pa gbogbo ilẹ aiye run; emi o si nà ọwọ mi sori rẹ, emi o si yi ọ lulẹ lati ori apata wá, emi o si ṣe ọ ni oke jijona.
26 Ki nwọn ki o má le mu okuta igun ile, tabi okuta ipilẹ ninu rẹ, ṣugbọn iwọ o di ahoro lailai, li Oluwa wi.
27 Ẹ gbe asia soke ni ilẹ na, fọn ipè lãrin awọn orilẹ-ède, sọ awọn orilẹ-ède di mimọ́ sori rẹ̀, pè awọn ijọba Ararati, Minni, ati Aṣkinasi sori rẹ̀, yàn balogun sori rẹ̀, mu awọn ẹṣin wá gẹgẹ bi ẹlẹnga ẹlẹgun.
28 Sọ awọn orilẹ-ède pẹlu awọn ọba Media di mimọ́ sori rẹ̀, awọn balẹ rẹ̀, ati gbogbo awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀.