4 Awọn ti a pa yio si ṣubu ni ilẹ awọn ara Kaldea, awọn ti a gun li ọ̀kọ, yio si ṣubu ni ita rẹ̀.
5 Nitori Israeli ati Juda, kì iṣe opó niwaju Ọlọrun wọn, niwaju Oluwa, awọn ọmọ-ogun; nitori ilẹ wọn (Babeli) ti kún fun ẹbi si Ẹni-Mimọ Israeli.
6 Ẹ salọ kuro lãrin Babeli, ki olukuluku enia ki o si gbà ọkàn rẹ̀ là: ki a máṣe ke nyin kuro ninu aiṣedede rẹ̀; nitori eyi li àkoko igbẹsan fun Oluwa; yio san ère iṣẹ fun u.
7 Babeli jẹ ago wura lọwọ Oluwa, ti o mu gbogbo ilẹ aiye yo bi ọ̀muti: awọn orilẹ-ède ti mu ninu ọti-waini rẹ̀; nitorina ni awọn orilẹ-ède nṣogo.
8 Babeli ṣubu, a si fọ ọ lojiji: ẹ hu fun u; ẹ mu ikunra fun irora rẹ̀, bi o jẹ bẹ̃ pe, yio san fun u.
9 Awa fẹ wò Babeli sàn, ṣugbọn kò sàn; ẹ kọ̀ ọ silẹ, ki ẹ si jẹ ki a lọ, olukuluku si ilẹ rẹ̀: nitori ẹbi rẹ̀ de ọrun, a si gbe e soke de awọsanma.
10 Oluwa mu ododo wa jade; ẹ wá, ẹ jẹ ki a si kede iṣẹ Oluwa Ọlọrun wa ni Sioni.