1 SEDEKIAH jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹrẹ si ijọba, o si jọba, ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah, ara Libna.
2 On si ṣe buburu niwaju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiakimu ti ṣe.
3 Nitori ibinu Oluwa, o ri bẹ̃ ni Jerusalemu ati Juda, titi o fi tì wọn jade kuro niwaju rẹ̀. Sedekiah si ṣọtẹ si ọba Babeli.
4 O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣu kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣu, Nebukadnessari, ọba Babeli de, on ati gbogbo ogun rẹ̀ si Jerusalemu, o si dó tì i, o si mọdi tì i yikakiri.
5 A si há ilu na mọ titi di ọdun ikọkanla Sedekiah ọba.
6 Ati li oṣu kẹrin li ọjọ kẹsan oṣu, ìyan mu gidigidi ni ilu, tobẹ̃ ti kò si onjẹ fun awọn enia ilẹ na.
7 Nigbana ni a fọ ilu, gbogbo awọn ologun si sá, nwọn si jade ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ẹnu ibode ãrin odi meji, ti o wà li ẹba ọgbà ọba, ṣugbọn awọn ara Kaldea yi ilu ka: nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ.