7 Nigbana ni a fọ ilu, gbogbo awọn ologun si sá, nwọn si jade ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ẹnu ibode ãrin odi meji, ti o wà li ẹba ọgbà ọba, ṣugbọn awọn ara Kaldea yi ilu ka: nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ.
8 Ṣugbọn ogun awọn ara Kaldea lepa ọba, nwọn si ba Sedekiah ni pẹtẹlẹ Jeriko, gbogbo ogun rẹ̀ si tuka kuro lọdọ rẹ̀.
9 Nwọn si mu ọba, nwọn si mu u goke wá si ọdọ ọba Babeli ni Ribla, ni ilẹ Hamati; o si sọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.
10 Ọba Babeli si pa awọn ọmọ Sedekiah niwaju rẹ̀: o pa gbogbo awọn ọlọla Juda pẹlu ni Ribla.
11 Pẹlupẹlu ọba Babeli fọ Sedekiah li oju; o si fi ẹ̀wọn dè e, o si mu u lọ si Babeli, o si fi sinu tubu titi di ọjọ ikú rẹ̀.
12 Njẹ li oṣu karun, li ọjọ kẹwa oṣu, ti o jẹ ọdun kọkandilogun Nebukadnessari, ọba Babeli, ni Nebusaradani, balogun iṣọ, ti o nsin ọba Babeli, wá si Jerusalemu.
13 O si kun ile Oluwa, ati ile ọba; ati gbogbo ile Jerusalemu, ati gbogbo ile nla li o fi iná sun.