5 Nitori bi ẹnyin ba tun ọ̀na ati ìwa nyin ṣe nitõtọ; ti ẹnyin ba ṣe idajọ otitọ jalẹ, ẹnikini si ẹnikeji rẹ̀.
6 Ti ẹnyin kò ba si ṣẹ́ alejo ni iṣẹ́, alainibaba ati opó, ti ẹnyin kò si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ni ibi yi, ti ẹnyin kò si rìn tọ ọlọrun miran si ipalara nyin.
7 Nigbana ni emi o mu nyin gbe ibi yi, ni ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin lai ati lailai.
8 Sa wò o, ẹnyin gbẹkẹle ọ̀rọ eke, ti kò ni ère.
9 Kohaṣepe, ẹnyin njale, ẹ npania, ẹ nṣe panṣaga, ẹ nbura eke, ẹ nsun turari fun Baali, ẹ si nrin tọ ọlọrun miran ti ẹnyin kò mọ̀?
10 Ẹnyin si wá, ẹ si duro niwaju mi ni ile yi, ti a fi orukọ mi pè! ẹnyin si wipe: Gbà wa, lati ṣe gbogbo irira wọnyi?
11 Ile yi, ti ẹ fi orukọ mi pè, o ha di iho olè li oju nyin? sa wò o, emi tikarami ti ri i, li Oluwa wi.