4 Iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi; enia le ṣubu li aidide mọ? tabi enia le pada, ki o má tun yipada mọ?
5 Ẽṣe ti awọn enia Jerusalemu yi sọ ipadasẹhin di ipẹhinda lailai? nwọn di ẹ̀tan mu ṣinṣin, nwọn kọ̀ lati pada.
6 Mo tẹti lélẹ, mo si gbọ́, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ titọ: kò si ẹnikan ti o ronupiwada buburu rẹ̀ wipe, kili emi ṣe? gbogbo nwọn yipo li ọ̀na wọn, bi akọ-ẹṣin ti nsare gburu sinu ogun.
7 Lõtọ ẹiyẹ àkọ li oju-ọrun mọ̀ akoko rẹ̀, àdaba ati ẹiyẹ lekeleke pẹlu alapandẹ̀dẹ sọ́ igba wiwá wọn; ṣugbọn enia mi kò mọ̀ idajọ Oluwa.
8 Bawo li ẹnyin ṣe wipe, Ọlọgbọ́n ni wa, ati ofin Oluwa mbẹ lọdọ wa? sa wò o nitõtọ! kalamu eke awọn akọwe ti sọ ofin di eke.
9 Oju tì awọn ọlọgbọ́n, idamu ba wọn a si mu wọn: sa wò o, nwọn ti kọ̀ ọ̀rọ Oluwa! ọgbọ́n wo li o wà ninu wọn?
10 Nitorina ni emi o fi aya wọn fun ẹlomiran, ati oko wọn fun awọn ti yio gbà wọn: nitori gbogbo wọn, lati ẹni kekere titi o fi de enia-nla, fi ara wọn fun ojukokoro, lati woli titi de alufa, gbogbo wọn nṣe ẹ̀tan.