1 ORI mi iba jẹ omi, ati oju mi iba jẹ orisun omije, ki emi le sọkun lọsan ati loru fun awọn ti a pa ninu ọmọbinrin enia mi!
2 A! emi iba ni buka ero ni iju, ki emi ki o le fi enia mi silẹ, ki nlọ kuro lọdọ wọn! nitori gbogbo nwọn ni panṣaga, ajọ alarekereke enia ni nwọn.
3 Nwọn si fà ahọn wọn bi ọrun fun eke; ṣugbọn nwọn kò ṣe akoso fun otitọ lori ilẹ, nitoripe nwọn ti inu buburu lọ si buburu nwọn kò si mọ̀ mi, li Oluwa wi.
4 Ẹ mã ṣọra, olukuluku nyin lọdọ aladugbo rẹ̀, ki ẹ má si gbẹkẹle arakunrin karakunrin: nitoripe olukuluku arakunrin fi arekereke ṣẹtan patapata, ati olukuluku aladugbo nsọ̀rọ ẹnilẹhin.
5 Ẹnikini ntàn ẹnikeji rẹ̀ jẹ, nwọn kò si sọ otitọ: nwọn ti kọ́ ahọn wọn lati ṣeke, nwọn si ti ṣe ara wọn lãrẹ lati ṣe aiṣedede.
6 Ibugbe rẹ mbẹ lãrin ẹ̀tan; nipa ẹ̀tan nwọn kọ̀ lati mọ̀ mi, li Oluwa wi.
7 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, sa wò o, emi o yọ́ wọn, emi o si dán wọn wò, nitori kili emi o ṣe fun ọmọbinrin enia mi.