23 Bayi li Oluwa wi, ki ọlọgbọ́n ki o má ṣogo nitori ọgbọ́n rẹ̀, bẹ̃ni ki alagbara ki o má ṣogo nitori agbara rẹ̀, ki ọlọrọ̀ ki o má ṣogo nitori ọrọ̀ rẹ̀.
24 Ṣugbọn ki ẹnikẹni ti yio ba ma ṣogo, ki o ṣe e ninu eyi pe: on ni oye, on si mọ̀ mi; pe, Emi li Oluwa ti nṣe ãnu ati idajọ ati ododo li aiye: nitori inu mi dùn ninu ohun wọnyi, li Oluwa wi.
25 Sa wò o, ọjọ mbọ̀ li Oluwa wi, ti emi o jẹ gbogbo awọn ti a kọ ni ilà pẹlu awọn alaikọla ni ìya;
26 Egipti ati Juda ati Edomu, ati awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, pẹlu gbogbo awọn ti ndá òṣu, ti ngbe aginju: nitori alaikọla ni gbogbo orilẹ-ède yi, ṣugbọn gbogbo ile Israeli jẹ alaikọla ọkàn.