8 Ahọn wọn dabi ọfa ti a ta, o nsọ ẹ̀tan, ẹnikini nfi ẹnu rẹ̀ sọ alafia fun ẹnikeji rẹ̀, ṣugbọn li ọkàn rẹ̀ o ba dè e.
9 Emi kì yio ha bẹ̀ wọn wò nitori nkan wọnyi? li Oluwa wi, ọkàn mi kì yio ha gbẹsan lara orilẹ-ède bi iru eyi?
10 Fun awọn oke-nla ni emi o gbe ẹkún ati ohùnrere soke, ati ẹkún irora lori papa oko aginju wọnnì, nitoriti nwọn jona, ẹnikan kò le kọja nibẹ, bẹ̃ni a kò gbọ́ ohùn ẹran-ọsin, lati ẹiyẹ oju-ọrun titi de ẹranko ti sa kuro, nwọn ti lọ.
11 Emi o sọ Jerusalemu di okiti àlapa, ati iho awọn ikõko, emi o si sọ ilu Juda di ahoro, laini olugbe.
12 Tani enia na ti o gbọ́n, ti o moye yi? ati tani ẹniti ẹnu Oluwa ti sọ fun, ki o ba le kede rẹ̀, pe: kili o ṣe ti ilẹ fi ṣegbe, ti o si sun jona bi aginju, ti ẹnikan kò kọja nibẹ?
13 Oluwa si wipe, nitoriti nwọn ti kọ̀ ofin mi silẹ ti mo ti gbe kalẹ niwaju wọn, ti nwọn kò si gbà ohùn mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò si rin ninu rẹ̀.
14 Ṣugbọn nwọn ti rin nipa agidi ọkàn wọn ati nipasẹ Baalimu, ti awọn baba wọn kọ́ wọn: