1 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:
2 “Lọ kéde sí etí ìgbọ́ àwọn Jérúsálẹ́mù:“ ‘Mo rántí ìfarasìn ìgbà èwe rẹ,gẹ́gẹ́ bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ mi bí i wúndíá àti bí o ṣe tẹ̀lé mi nínú aṣálẹ̀ àti nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.
3 Ísírẹ́lì jẹ́ mímọ́ sí Olúwa, àkọ́kọ́èṣo ìkórè rẹ̀, gbogbo ẹnikẹ́ni tí óbá jẹ run ni a ó dá lẹ́bi, ìpọ́njúyóò dé bá wọn,’ ”bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
4 Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jákọ́bùàti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Ísírẹ́lì.