Jeremáyà 5:1-7 BMY

1 “Lọ sókè àti sódò àwọn òpó Jérúsálẹ́mùWò yíká, kí o sì mọ̀,kí o sì wá kiriBí o bá le è rí ẹnìkan,tí ó jẹ́ olóòótọ́ àti olódodo,N ó dárí jìn ìlú yìí.

2 Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí Olúwa ti ń bẹ,’síbẹ̀ wọ́n búra èké.”

3 Olúwa, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n.Ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà.Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ,wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.

4 Èmi sì rò pé, “talákà ni àwọn yìíwọn kò lóyenítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa,àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.

5 Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ,n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀;ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà Olúwaàti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.”Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́,wọ́n sì ti já ìdè.

6 Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n,ìkokò ihà yóò sì pa wọ́n run,ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yínẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,nítorí àìgbọ́ràn yín pọ,apadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.

7 “Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́?Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.Mo pèṣè fún gbogbo àìní wọn,síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágàwọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbérè.