5 Ati awọn, bi nwọn o gbọ́, tabi bi nwọn o kọ̀, (nitori ọlọtẹ̀ ile ni nwọn) sibẹ nwọn o mọ̀ pe woli kan ti wà larin wọn.
6 Ati iwọ, ọmọ enia, máṣe bẹ̀ru wọn, bẹ̃ni ki o máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bi ẹgun ọgàn ati oṣuṣu tilẹ pẹlu rẹ, ti iwọ si gbe ãrin akẽkẽ: máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bẹ̃ni ki o máṣe foya wiwò wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọtẹ̀ ile.
7 Iwọ o si sọ ọ̀rọ mi fun wọn, bi nwọn o gbọ́, tabi bi wọn o kọ̀: nitoriti nwọn jẹ ọlọtẹ̀.
8 Ṣugbọn iwọ, ọmọ enia, gbọ́ ohun ti mo sọ fun ọ; Iwọ máṣe jẹ ọlọtẹ̀ bi ọlọtẹ̀ ile nì: ya ẹ̀nu rẹ, ki o si jẹ ohun ti mo fi fun ọ.
9 Nigbati mo wò, si kiye si i, a ran ọwọ́ kan si mi; si kiye si i, iká-iwé kan wà ninu rẹ̀.
10 O si tẹ́ ẹ siwaju mi, a si kọ ọ ninu ati lode: a si kọ ohùn-reré-ẹkun, ati ọ̀fọ, ati egbé.