1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2 Njẹ, iwọ ọmọ enia, iwọ o ha ṣe idajọ, iwọ o ha ṣe idajọ ilu ẹlẹjẹ na? nitõtọ, iwọ o jẹ ki o mọ̀ ohun irira rẹ̀ gbogbo.
3 Nitorina, iwọ wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Ilu ti o ta ẹjẹ silẹ lãrin rẹ̀, ki akoko rẹ̀ ki o le de, o si ṣe oriṣa si ara rẹ̀ lati sọ ara rẹ̀ di aimọ́.
4 Iwọ ti di ẹlẹbi niti ẹjẹ rẹ ti iwọ ti ta silẹ; iwọ si ti sọ ara rẹ di aimọ́ niti òriṣa rẹ ti iwọ ti ṣe, iwọ si ti mu ọjọ rẹ summọ tosí, iwọ si ti dé ọdun rẹ: nitorina ni mo ṣe sọ ọ di ẹgàn si awọn keferi, ati ẹsín si gbogbo ilẹ.
5 Awọn ti o sunmọ tosí, ati awọn ti o jìna si ọ, yio fi ọ ṣẹ̀sin, iwọ ti a bà orukọ rẹ̀ jẹ, ti a si bà ninu jẹ pupọ.
6 Kiyesi i, awọn ọmọ-alade Israeli, olukuluku ninu agbara rẹ̀ wà ninu rẹ lati ta ẹjẹ silẹ.
7 Ninu rẹ ni nwọn kò ka baba ati iyá si: lãrin rẹ ni nwọn ti ni awọn alejo lara: ninu rẹ ni nwọn ti bà alaini-baba ati opo ninu jẹ.