46 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o mu ẹgbẹ kan tọ̀ wọn wá, emi o si fi wọn fun wọn lati kó wọn lọ, ati lati bà wọn jẹ.
47 Ẹgbẹ na yio si sọ wọn li okuta, nwọn o si fi idà pa wọn; nwọn o pa awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn obinrin, nwọn o si fi iná kun ile wọn.
48 Bayi li emi o jẹ ki ìwa ifẹkufẹ mọ lãrin ilẹ na, ki a ba le kọ́ gbogbo obinrin, ki nwọn má bà ṣe bi ifẹkufẹ nyin.
49 Nwọn o si san ẹ̀san ìwa ifẹkufẹ nyin si ori nyin, ẹnyin o si rù ẹ̀ṣẹ oriṣa nyin; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.