5 Emi o si sọ Rabba di ibujẹ fun ibakasiẹ, ati awọn ọmọ Ammoni di ibùsun fun agbo-ẹran: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
6 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti iwọ ti pa atẹ́wọ, ti o si ti fi ẹsẹ kì ilẹ, ti o si yọ̀ li ọkàn pẹlu gbogbo aránkan rẹ si ilẹ Israeli:
7 Kiye si i, nitorina, emi o nà ọwọ́ mi le ọ, emi o si fi ọ fun awọn keferi fun ikogun; emi o si ke ọ kuro lãrin awọn enia, emi o si jẹ ki o ṣegbé kuro ninu ilẹ gbogbo: emi o pa ọ run; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
8 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe Moabu ati Seiri wipe, Kiye si i, ile Juda dabi gbogbo awọn keferi;
9 Nitorina, kiye si i, emi o ṣi ìha Moabu kuro lati awọn ilu gbogbo, kuro ninu awọn ilu rẹ̀ ti o wà li àgbegbe rẹ̀, ogo ilẹ na, Bet-jeṣimoti, Baalimeoni, ati Kiri-ataimu,
10 Fun awọn ọmọ ìla-orun, pẹlu awọn ara Ammoni, emi o si fi wọn fun ni ni iní; ki a má ba ranti awọn ara Ammoni lãrin orilẹ-ède mọ.
11 Emi o si mu idajọ ṣẹ si Moabu lara, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.