17 Ọkàn rẹ gbe soke nitori ẹwà rẹ, o ti bà ọgbọ́n rẹ jẹ nitori dídan rẹ; emi o bì ọ lulẹ, emi o gbe ọ kalẹ niwaju awọn ọba, ki nwọn ba le wò ọ.
18 Iwọ ti bà ibi mimọ́ rẹ jẹ nipa ọ̀pọlọpọ aiṣedẽde rẹ, nipa aiṣedẽde òwo rẹ; nitorina emi o mu iná jade lati ãrin rẹ wá, yio jó ọ run, emi o si sọ ọ di ẽru lori ilẹ loju gbogbo awọn ti o wò ọ:
19 Gbogbo awọn ti o mọ̀ ọ lãrin awọn orilẹ-ède li ẹnu o yà si ọ: iwọ o jẹ ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́ lailai.
20 Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
21 Ọmọ enia, gbé oju rẹ si Sidoni, ki o si sọtẹlẹ si i,
22 Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Sa wò o, Emi doju kọ ọ, iwọ Sidoni; a o si ṣe mi logo li ãrin rẹ, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o bá ti mu idajọ mi ṣẹ ninu rẹ̀, ti a o si yà mi si mimọ́ ninu rẹ̀.
23 Emi o si rán àjakálẹ àrun sinu rẹ̀, ati ẹjẹ ni igboro rẹ̀; a o si fi idà pa awọn si a ṣá li ọgbẹ li ãrin rẹ̀ lori rẹ̀ nihà gbogbo; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.