1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
2 Ọmọ enia, sọtẹlẹ ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹ wu, Egbé fun ọjọ na!
3 Nitori ọjọ na sunmọ tosí, ani ọjọ Oluwa sunmọ tosi, ọjọ ikũkũ ni; yio jẹ akoko ti awọn keferi.
4 Idà yio si wá sori Egipti, irora nla yio wà ni Etiopia, nigbati awọn ti a pa yio ṣubu ni Egipti, nwọn o si mu ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ lọ kuro, ipilẹ rẹ̀ yio si wó lulẹ.
5 Etiopia, ati Libia, ati Lidia, ati gbogbo awọn olùranlọ́wọ, ati Kubu, ati awọn enia ilẹ na ti o mulẹ yio ti ipa idà ṣubu pẹlu wọn.
6 Bayi li Oluwa wi; Awọn pẹlu ti nwọn gbe Egipti ró yio ṣubu; ati igberaga agbara rẹ̀ yio sọkalẹ: lati Migdoli lọ de Siene ni nwọn o ti ipà idà ṣubu ninu rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.
7 Nwọn o si di ahoro li ãrin awọn ilẹ ti o di ahoro, ilu rẹ̀ yio si wà li àrin awọn ilu ti o di ahoro.