12 Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun awọn ọmọ enia rẹ, ododo olododo kì yio gbà a là li ọjọ irekọja rẹ̀: bi o ṣe ti ìwa buburu enia buburu, on kì yio ti ipa rẹ̀ ṣubu li ọjọ ti o yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀: bẹ̃ni olododo kì yio là nipa ododo rẹ̀ li ọjọ ti o dẹṣẹ.
13 Nigbati emi o wi fun olododo pe, yiyè ni yio yè, bi o ba gbẹkẹle ododo ara rẹ̀, ti o si ṣe aiṣedẽde, gbogbo ododo rẹ̀ li a kì yio ranti mọ, ṣugbọn nitori aiṣedẽde ti o ti ṣe, on o ti itori rẹ̀ kú.
14 Ẹ̀wẹ, nigbati emi wi fun enia buburu pe, Kikú ni iwọ o kú; bi on ba yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o si ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ;
15 Bi enia buburu ba mu ògo padà, ti o si san ohun ti o ti jí padà, ti o si nrin ni ilana ìye, li aiṣe aiṣedẽde; yiyè ni yio yè, on kì o kú.
16 A kì yio ṣe iranti gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ndá fun u: on ti ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ; on o yè nitõtọ.
17 Sibẹ awọn ọmọ enia rẹ wipe, Ọ̀na Oluwa kò dọgba: ṣugbọn bi o ṣe ti wọn ni, ọ̀na wọn kò dọgba.
18 Nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀ ti o si ṣe aiṣedẽde, on o ti ipa rẹ̀ kú.