6 Ṣugbọn bi oluṣọ́ na bá ri ti idà mbọ̀, ti kò si fun ipè, ti a kò si kìlọ fun awọn enia; bi idà ba de, ti o ba si mu ẹnikẹni lãrin wọn, a mu u kuro nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere lọwọ oluṣọ́ na.
7 Bẹ̃ni, iwọ ọmọ enia, emi ti fi ọ ṣe oluṣọ́ fun ile Israeli; nitorina iwọ o gbọ́ ọ̀rọ li ẹnu mi, iwọ o si kìlọ fun wọn lati ọdọ mi.
8 Nigbati emi ba wi fun enia buburu pe, Iwọ enia buburu, kikú ni iwọ o kú, bi iwọ kò bá sọ̀rọ lati kìlọ fun enia buburu na ki o kuro li ọ̀na rẹ̀, enia buburu na yio kú nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ.
9 Ṣugbọn, bi iwọ ba kìlọ fun enia buburu na niti ọ̀na rẹ̀ lati pada kuro ninu rẹ̀, bi on kò ba yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀, on o kù nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn iwọ ti gbà ọkàn rẹ là.
10 Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun ile Israeli; pe, Bayi li ẹnyin nwi, pe, Bi irekọja ati ẹ̀ṣẹ wa ba wà lori wa, ti awa si njoró ninu wọn, bawo li a o ti ṣe le wà lãye.
11 Sọ fun wọn pe, Bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, emi kò ni inu-didun ni ikú enia buburu, ṣugbọn ki enia buburu yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀ ki o si yè: ẹ yipada, ẹ yipada kuro ninu ọ̀na buburu nyin; nitori kini ẹnyin o ṣe kú, Ile Israeli?
12 Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun awọn ọmọ enia rẹ, ododo olododo kì yio gbà a là li ọjọ irekọja rẹ̀: bi o ṣe ti ìwa buburu enia buburu, on kì yio ti ipa rẹ̀ ṣubu li ọjọ ti o yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀: bẹ̃ni olododo kì yio là nipa ododo rẹ̀ li ọjọ ti o dẹṣẹ.