21 Nitoriti ẹnyin ti fi ẹgbẹ́ ati ejiká gbún, ti ẹ si ti fi iwo nyin kàn gbogbo awọn ti o li àrun titi ẹ fi tú wọn kakiri.
22 Nitorina ni emi o ṣe gbà ọwọ́-ẹran mi là, nwọn kì yio si jẹ ijẹ́ mọ, emi o si ṣe idajọ lãrin ẹran ati ẹran.
23 Emi o si gbe oluṣọ́ agutan kan soke lori wọn, on o si bọ́ wọn, ani Dafidi iranṣẹ mi; on o bọ́ wọn, on o si jẹ oluṣọ́ agutan wọn.
24 Emi Oluwa yio si jẹ Ọlọrun wọn, ati Dafidi iranṣẹ mi o jẹ ọmọ-alade li ãrin wọn, emi Oluwa li o ti sọ ọ.
25 Emi o si ba wọn da majẹmu alafia, emi o si jẹ ki awọn ẹranko buburu dasẹ ni ilẹ na: nwọn o si ma gbe aginju li ailewu, nwọn o si sùn ninu igbó.
26 Emi o si ṣe awọn ati ibi ti o yi oke mi ká ni ibukún; emi o si jẹ ki ojò ki o rọ̀ li akoko rẹ̀, òjo ibukún yio wà.
27 Igi igbẹ́ yio si so eso rẹ̀, ilẹ yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá, nwọn o si wà li alafia ni ilẹ wọn, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o ti ṣẹ́ èdídi àjaga wọn, ti emi o si ti gbà wọn lọwọ awọn ti nwọn nsìn bi ẹrú.