6 Nitorina sọtẹlẹ niti ilẹ Israeli, ki o si wi fun awọn oke nla, ati fun awọn oke kékèké, fun awọn odò, ati fun awọn afonifoji, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Wò o, emi ti sọ̀rọ ninu owu mi, ati ninu irúnu mi, nitori ti ẹnyin ti rù itiju awọn keferi.
7 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi ti gbe ọwọ́ mi soke, Nitõtọ awọn keferi ti o yi nyin ka, awọn ni yio rù itiju wọn.
8 Ṣugbọn ẹnyin, oke Israeli, ẹnyin o yọ ẹka jade, ẹ o si so eso nyin fun Israeli enia mi; nitori nwọn fẹrẹ̀ de.
9 Si kiyesi i, emi wà fun nyin, emi o si yipadà si nyin, a o si ro nyin, a o si gbìn nyin:
10 Emi o si mu enia bi si i lori nyin, gbogbo ile Israeli, ani gbogbo rẹ̀: awọn ilu yio si ni olugbe, a o si kọ́ ibi ti o di ahoro:
11 Emi o si mu enia ati ẹranko bi si i lori nyin; nwọn o si pọ̀ si i, nwọn o si rẹ̀: emi o si mu nyin joko ni ibugbe nyin, bi ti atijọ, emi o si ṣe si nyin jù igbà ibẹ̀rẹ nyin lọ: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
12 Nitõtọ, emi o mu ki enia rìn lori nyin, ani Israeli enia mi; nwọn o si ni ọ, iwọ o si jẹ iní wọn, iwọ kì yio si gbà wọn li ọmọ mọ lati isisiyi lọ.