1 O si mu mi pada lọna ẹnu-ọ̀na ibi mimọ́ ti ode ti o kọju si ila-õrun; o si tì.
2 Oluwa si wi fun mi pe; Ẹnu-ọ̀na yi yio wà ni titì, a kì yio ṣi i, ẹnikan kì yio si gbà a wọ inu rẹ̀; nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti gbà a wọ inu rẹ̀, yio si wà ni titì.
3 Fun ọmọ-alade ni; ọmọ-alade, on ni yio joko ninu rẹ̀ lati jẹ akara niwaju Oluwa; yio wọ̀ ọ lati ọ̀na iloro ẹnu-ọ̀na na, yio si jade lati ọ̀na rẹ̀ na lọ.
4 O si mu mi wá ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa siwaju ile na; mo si wò, si kiyesi i, ogo Oluwa kun ile Oluwa: mo si doju mi bolẹ.
5 Oluwa si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi iyè rẹ si i, si fi oju rẹ wò, si fi eti rẹ gbọ́ ohun gbogbo ti emi ti sọ fun ọ niti gbogbo aṣẹ ile Oluwa, ati ti gbogbo ofin rẹ̀; si fi iyè rẹ si iwọ̀nu ile nì, pẹlu gbogbo ijadelọ ibi-mimọ́ na.
6 Iwọ o si wi fun awọn ọlọ̀tẹ, ani fun ile Israeli, pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; ki gbogbo ohun-irira nyin to fun nyin, ile Israeli,
7 Niti pe ẹ mu ọmọ-ajèji, alaikọla aiya, ati alaikọla ara wa, lati wà ni ibi-mimọ́ mi, lati sọ ọ di alailọ̀wọ, ani ile mi, nigbati ẹ rú akara mi, ọ̀ra ati ẹjẹ, nwọn si bà majẹmu mi jẹ nipa gbogbo ohun-irira nyin.