15 Idà mbẹ lode, ajakálẹ àrun ati iyàn si mbẹ ninu: ẹniti o wà li oko yio kú nipa idà; ẹniti o wà ninu ilu, iyàn ati ajakálẹ àrun ni yio si jẹ ẹ run.
16 Ṣugbọn awọn ti o bọ́ ninu wọn yio salà, nwọn o si wà lori oke bi adabà afonifoji, gbogbo nwọn o ma gbãwẹ, olukuluku nitori aiṣedede rẹ̀.
17 Gbogbo ọwọ́ ni yio rọ, gbogbo ẽkun ni yio si di ailera bi omi.
18 Aṣọ ọ̀fọ ni nwọn o fi gbajá pẹlu; ìbẹru ikú yio si bò wọn mọlẹ; itiju yio si wà loju gbogbo wọn, ẽpá yio si wà li ori gbogbo wọn.
19 Nwọn o sọ fadaka wọn si igboro, wura wọn li a o si mu kuro; fadaka wọn ati wura wọn kì yio si le gbà wọn là li ọjọ ibinu Oluwa: nwọn kì yio tẹ́ ọkàn wọn lọrùn, bẹ̃ni nwọn kì yio kún inu wọn; nitori on ni idùgbolu aiṣedede wọn.
20 Bi o ṣe ti ẹwà ohun ọṣọ́ rẹ̀ ni, o gbe e ka ibi ọlanla: ṣugbọn nwọn yá ere irira wọn ati ohun ikorira wọn ninu rẹ̀: nitorina li emi ṣe mu u jina si wọn.
21 Emi o si fi i si ọwọ́ awọn alejo fun ijẹ, ati fun enia buburu aiye fun ikogun: nwọn o si bà a jẹ.