Jer 17:21-27 YCE

21 Bayi li Oluwa wi, Ẹ kiyesi li ọkàn nyin, ki ẹ máṣe ru ẹrù li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe mu u wá ninu ẹnu-bode Jerusalemu:

22 Bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe gbe ẹrù jade kuro ninu ile nyin li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe iṣẹkiṣẹ, ṣugbọn ki ẹ yà ọjọ isimi si mimọ́, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun awọn baba nyin.

23 Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, nwọn kò si tẹti silẹ, nwọn mu ọrun wọn le, ki nwọn ki o má ba gbọ́, ati ki nwọn o má bà gba ẹ̀kọ́.

24 Yio si ṣe bi ẹnyin ba tẹtisilẹ gidigidi si mi, li Oluwa wi, ti ẹ kò ba ru ẹrù kọja ni ẹnu-bode ilu yi li ọjọ isimi, ti ẹ ba si yà ọjọ isimi si mimọ, ti ẹ kò si ṣe iṣẹkiṣẹ ninu rẹ̀,

25 Nigbana ni nwọn o wọ ẹnu-bode ilu yi, ani ọba, ati ijoye ti o joko lori itẹ Dafidi, awọn ti ngun kẹ̀kẹ ati ẹṣin, awọn wọnyi pẹlu ijoye wọn, awọn ọkunrin Juda, ati olugbe Jerusalemu: nwọn o si ma gbe ilu yi lailai.

26 Nwọn o si wá lati ilu Juda wọnni, ati lati àgbegbe Jerusalemu yikakiri, ati lati ilẹ Benjamini, lati pẹtẹlẹ, ati lati oke, ati lati gusu wá, nwọn o si mu ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹran ati turari, ati awọn wọnyi ti o mu iyìn wá si ile Oluwa.

27 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti emi, lati ya ọjọ isimi si mimọ́, ti ẹ kò si ru ẹrù, ti ẹ kò tilẹ wọ ẹnu-bode Jerusalemu li ọjọ isimi; nigbana ni emi o da iná ni ẹnu-bode wọnni, yio si jo ãfin Jerusalemu run, a kì o si pa a.