7 Ibukun ni fun ẹniti o gbẹkẹle Oluwa, ti o si fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀!
8 Yio si dabi igi ti a gbìn lẹba omi, ti o nà gbòngbo rẹ̀ lẹba odò, ti kì yio bẹ̀ru bi õru ba de, ṣugbọn ewe rẹ̀ yio tutu, kì yio si ni ijaya ni ọdun ọ̀dá, bẹ̃ni kì yio dẹkun lati ma so eso.
9 Ọkàn enia kún fun ẹ̀tan jù ohun gbogbo lọ, o si buru jayi! tani o le mọ̀ ọ?
10 Emi, Oluwa, ni iwá awari ọkàn enia, emi ni ndan inu wò, ani lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ati gẹgẹ bi eso iṣe rẹ̀.
11 Bi aparo ti isaba lori ẹyin ti kò yin, bẹ̃ gẹgẹ ni ẹniti o kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kì iṣe ni ododo; yio fi i silẹ lagbedemeji ọjọ rẹ̀, ati ni opin rẹ̀ yio jẹ aṣiwere.
12 Itẹ́ ogo! ibi giga lati ipilẹsẹ ni ibi ile mimọ́ wa!
13 Oluwa ni ireti Israeli! gbogbo awọn ti o kọ̀ ọ silẹ yio dãmu, awọn ti o yẹ̀ kuro lọdọ mi, ni a o kọ orukọ wọn sinu ẽkuru, si ori ilẹ, nitori nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, orisun omi ìye.